15 Ipamọra pipẹ li a fi iyi ọmọ-alade li ọkàn pada, ahọn ti o kunna ni ifọ egungun.
16 Bi iwọ ba ri oyin, jẹ eyi ti o to fun ọ, ki o má ba su ọ, iwọ a si bì i.
17 Fà ẹṣẹ sẹhin kuro ni ile aladugbo rẹ; ki agara rẹ o má ba da a, on a si korira rẹ.
18 Ẹniti o jẹri eke si ẹnikeji rẹ̀, ni olugboro, ati idà, ati ọfà mimu.
19 Igbẹkẹle alaiṣõtọ enia ni ìgba ipọnju, o dabi ehin ti o ṣẹ́, ati ẹsẹ̀ ti o yẹ̀ lori ike.
20 Bi ẹniti o bọ aṣọ nigba otutu, ati bi ọti-kikan ninu ẽru, bẹ̃li ẹniti nkọrin fun ẹniti inu rẹ̀ bajẹ.
21 Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba si gbẹ ẹ, fun u li ohun mimu.