18 Ẹniti o jẹri eke si ẹnikeji rẹ̀, ni olugboro, ati idà, ati ọfà mimu.
19 Igbẹkẹle alaiṣõtọ enia ni ìgba ipọnju, o dabi ehin ti o ṣẹ́, ati ẹsẹ̀ ti o yẹ̀ lori ike.
20 Bi ẹniti o bọ aṣọ nigba otutu, ati bi ọti-kikan ninu ẽru, bẹ̃li ẹniti nkọrin fun ẹniti inu rẹ̀ bajẹ.
21 Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba si gbẹ ẹ, fun u li ohun mimu.
22 Nitoriti iwọ o kó ẹyin iná jọ si ori rẹ̀, Oluwa yio san fun ọ.
23 Afẹfẹ ariwa mu òjo wá, bẹ̃li ahọn isọ̀rọ-ẹni-lẹhin imu oju kikoro wá.
24 O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.