23 Afẹfẹ ariwa mu òjo wá, bẹ̃li ahọn isọ̀rọ-ẹni-lẹhin imu oju kikoro wá.
24 O san lati joko ni igun òke àja, jù pẹlu onija obinrin lọ ninu ile ajumọgbe.
25 Bi omi tutu si ọkàn ti ongbẹ ngbẹ, bẹ̃ni ihin-rere lati ilu okere wá.
26 Olododo ti o ṣipo pada niwaju enia buburu, o dabi orisun ti o wú, ati isun-omi ti o bajẹ.
27 Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni.
28 Ẹniti kò le ṣe akoso ara rẹ̀, o dabi ilu ti a wo lulẹ, ti kò si li odi.