4 Mu idarọ kuro ninu fadaka, ohun-elo yio si jade fun alagbẹdẹ fadaka.
5 Mu enia buburu kuro niwaju ọba, a o si fi idi itẹ́ rẹ̀ kalẹ ninu ododo.
6 Máṣe ṣefefe niwaju ọba, má si ṣe duro ni ipò awọn enia nla.
7 Nitoripe, o san ki a wi fun ọ pe, wá soke nihin, jù ki a fà ọ tì sẹhin niwaju ọmọ-alade ti oju rẹ ti ri.
8 Máṣe jade lọ kankan lati jà, ki iwọ ki o má ba ṣe alaimọ̀ eyiti iwọ o ṣe li opin rẹ̀, nigbati aladugbo rẹ yio dojutì ọ.
9 Ba ẹnikeji rẹ ja ìja rẹ̀; ṣugbọn aṣiri ẹlomiran ni iwọ kò gbọdọ fihàn.
10 Ki ẹniti o ba gbọ́ ki o má ba dojuti ọ, ẹ̀gan rẹ kì yio si lọ kuro lai.