5 Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀.
6 Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀.
7 Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o.
8 Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro.
9 Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si.
10 Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀.
11 Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin.