1 ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi.
2 Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́.
3 Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ:
4 Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji.
5 Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú.