12 Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi:
13 Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi.
14 Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ.
15 Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ.
16 Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita.
17 Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ.
18 Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ.