17 Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ.
18 Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ.
19 Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.
20 Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra?
21 Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo.
22 Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu.
23 Yio kú li aigbà ẹkọ́, ati ninu ọ̀pọlọpọ were rẹ̀ yio si ma ṣina kiri.