16 Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀:
17 Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ,
18 Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika,
19 Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin.
20 Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:
21 Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ.
22 Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ.