14 Ó sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”
15 Hánà dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” “Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni.
16 Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”
17 Élì dáhùn pé, “Má a lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”
18 Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọbinrin náà bá tirẹ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.
19 Wọ́n sì díde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rámà: Elikánà si mọ aya rẹ̀: Olúwa sì rántì rẹ̀.
20 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, pé, “Nítorí tí mo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”