22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrin àwọn ẹrù.”
23 Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàárin àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè.
24 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàárin gbogbo àwọn ènìyàn.”Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”
25 Sámúẹ́lì ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.
26 Ṣọ́ọ̀lù náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gíbíà. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín.
27 Ṣùgbọ́n àwọn oníjàgbọ̀n kan wí pé, “Báwo ni ẹni yìí yóò ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gan rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù fọwọ́ lẹ́rán.