6 Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, nínú agbára, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀.
7 Bí ìwọ bá ti rí àmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.
8 “Lọ ṣáájú mi sí Gílgálì. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”
9 Bí Ṣọ́ọ̀lù ti yípadà láti fi Sámúẹ́lì sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Ṣọ́ọ̀lù padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà.
10 Nígbà tí wọ́n dé òkè náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àṣọtẹ́lẹ̀.
11 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kíṣì yìí. Ṣé Ṣọ́ọ̀lù wà lára àwọn wòlíì ní?”
12 Ọkùnrin kan tí ó ń gbé níbẹ̀ dáhùn pé, “Ta ni baba wọn?” Ó ti di ohun tí a fi ń dáṣà pé, ǹjẹ́ Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì bí?