6 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè.
7 Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyọyọ sí gbogbo Ísírẹ́lì nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Ṣọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.
8 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì kó wọn jọ ní Bésékì, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀dógún. (300,000) àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún (30,000).
9 Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó wá pé, “Sọ fún àwọn ọkùnrin Jabesi-Gílíádì pé, ní àkókò tí oòrùn bá mú lọ́la, àwa yóò gbà yín sílẹ̀.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà lọ tí wọ́n sì sọ èyí fún àwọn ọkùnrin Jábésì, inú wọn sì dùn.
10 Wọ́n sọ fún àwọn ará Ámónì pé, “Àwa yóò fi ara wa fún un yín ní ọ̀la, kí ẹ̀yin kí ó ṣe gbogbo èyí tí ó tọ́ lójú yín sí wa.”
11 Ní ọjọ́ kejì Ṣọ́ọ̀lù pín àwọn ọkùnrin rẹ̀ sí ipa mẹ́ta, wọ́n sì ya wọ àgọ́ àwọn ará Ámónì ní ìṣọ́ òwúrọ̀, wọ́n sì pa wọ́n títí di ìmóju ọjọ́. Àwọn tó kù wọ́n sì fọ́nká, tó bẹ́ẹ̀ tí méjì wọn kò kù sí ibìkan.
12 Àwọn ènìyàn sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Ta ni ó béèrè wí pé, Ṣọ́ọ̀lù yóò ha jọba lórí wa? Mú àwọn ọkùnrin náà wá, a ó sì pa wọ́n.”