22 Ṣọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dáfídì ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsìn yìí jẹ́ àna ọba.’ ”
23 Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dáfídì. Ṣùgbọ́n Dáfídì wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”
24 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sọ fún un ohun tí Dáfídì sọ,
25 Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Sọ fún Dáfídì pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn ún Fílístínì lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀ta rẹ̀.’ ” Èrò Ṣọ́ọ̀lù ni wí pé kí Dáfídì ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.
26 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dáfídì, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá,
27 Dáfídì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Fílístínì. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó baà lè jẹ́ àna ọba. Ṣọ́ọ̀lù sì fi ọmọ obìnrin Míkálì fún un ní aya.
28 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì tí ọmọbìnrin rẹ̀ Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì,