1 Hánà sì gbàdúrà pé:“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;Ìwọ agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀ta mi,nítorí ti èmi yọ̀ ni igbala rẹ̀
2 “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;kò sí ẹlòmíràn bí kò se ìwọ;kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.
3 “Má ṣe halẹ̀;má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jádenítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.
4 “Ọrun àwọn alágbára ti ṣẹ́,àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.