30 “Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.
31 Kíyèsí i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ.
32 Nínú wàhálà ni ìwọ yóò fí ìlará wó gbogbo ọlá ti Ọlọ́run yóò fi fún Ísírẹ́lì; kì yóò sì sí arúgbó kan nínú ilé baba rẹ láéláé.
33 Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ni ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sunkún yọ lójú àti láti banújẹ́: Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.
34 “ ‘Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì, yóò jẹ́ àmì fún ọ, àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà.
35 Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi: Èmi yóò fi ẹṣẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo.
36 Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”