15 Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀ta Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.”
16 Nígbà náà ni Jónátanìf bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dáfídì láti sírò”
17 Jónátanì mú kí Dáfídì tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní síi, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀.
18 Nígbà náà ni Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a ó ò fẹ́ ọ kù, nítorí àyè rẹ yóò ṣófo.
19 Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí bi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Ésélù.
20 Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan.
21 Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún-un wí pé, ‘wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ;’ kó wọn wá síbí kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewú.