32 Jónátanì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?”
33 Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jónátánì láti gún un pa. Nígbà náà ni Jónátanì mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dáfídì ni.
34 Bẹ́ẹ̀ ni Jónátanì sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dáfídì, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.
35 Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jónátanì jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dáfídì ti fí àdéhùn sí, ọmọdekùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀.
36 Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀.
37 Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jónátanì ta, Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”
38 Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jónátanì sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá.