35 Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jónátanì jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dáfídì ti fí àdéhùn sí, ọmọdekùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀.
36 Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀.
37 Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jónátanì ta, Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”
38 Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jónátanì sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá.
39 (Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jónátanì àti Dáfídì ni ó mọ ọ̀ràn náà.)
40 Jónátanì sì fí apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú Para.”
41 Bí ọmọdékùnrin náà ti lọ tán, Dáfídì sì dìde láti ibi òkúta náà, ó sì wólẹ̀, ó sì tẹríba ní ìdojúbolẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jónátanì: wọ́n sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì jùmọ̀ sunkún, èkín-ín-ní pẹ̀lú ikejì rẹ̀, ṣùgbọ́n áfídì sunkún púpọ̀ jù.