1 Sámúẹ́lì 21:3-9 BMY

3 Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn ún tabi ohunkohun tí o bá rí.”

4 Àlùfáà náà sí dá Dáfídì lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́; Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pá ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”

5 Dáfídì sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin nígbàkùúgbà ti mo bá jáde ìrìn-àjò, gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, pàápàá nígbà ìrìn-àjò kékèké; kò há ní mọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ lónìí bí?”

6 Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fí àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn nibẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.

7 Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dá dúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dóégì, ará Édómù olórí nínú àwọn darandaran Ṣọ́ọ̀lù.

8 Dáfídì sì tún wí fún Áhímélékì pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.”

9 Àlùfáà náà sì wí pé, “Idàn Gòláyátì ará Fílístínì tí ó pa ní àfonífojì Élà ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn Éródù; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.”Dáfídì sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”