11 Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?”Òun sì wí pé, “Mú Sámúẹ́lì gòkè wá fún mi.”
12 Nígbà tí obìnrin náà sì rí Sámúẹ́lì, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Ṣọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù ni ìwọ jẹ́.”
13 Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?”Obìnrin náà sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi rí ẹ̀mí kan tí ó ti ilẹ̀ wá.”
14 Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.”Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.”Ṣọ́ọ̀lù sì mọ̀ pé, Sámúẹ́lì ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.
15 Sámúẹ́lì sì i wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?”Ṣọ́ọ̀lù sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Fílístínì ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”
16 Sámúẹ́lì sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.
17 Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dáfídì.