1 Sámúẹ́lì 28:3-9 BMY

3 Sámúẹ́lì sì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rámà ní ìlú rẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.

4 Àwọn Fílístínì sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣúnémù: Ṣọ́ọ̀lù sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gílíbóà.

5 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì rí ogun àwọn Fílístínì náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

6 Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Úrímù tàbí nípa àwọn wòlíì.

7 Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mi abókúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Ẹ́ńdórì tí ó ní ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀.”

8 Ṣọ́ọ̀lù sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

9 Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé “Wò ó, ìwọ sáà mọ ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ṣe, bí òun ti gé àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èé ha ṣe tí ìwọ dẹ́kùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”