6 Olúwa sì tún pè é, “Sámúẹ́lì!” Sámúẹ́lì tún dìde ó tọ Élì lọ, ó sì wí pé, “Èmi nì yí, nítorí tí ìwọ pè mí.”“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”
7 Ní àkókò yìí Sámúẹ́lì kò tíì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.
8 Olúwa pe Sámúẹ́lì ní ìgbà kẹ́tà, Sámúẹ́lì sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì ó sì wí pé, “Èmi nì yí; nítorí tí ìwọ pè mí.”Nígbà náà ni Élì wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà.
9 Nítorí náà Élì sọ fún Sámúẹ́lì, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìrànṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Sámúẹ́lì lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.
10 Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì!”Nígbà náà ni Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Má a wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”
11 Olúwa sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Ísírẹ́lì tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro.
12 Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Élì ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.