5 A sì kó àwọn aya Dáfídì méjèèjì nígbèkùn lọ, Áhínóámù ará Jésírẹ́lì àti Ábígáílì aya Nábálì ará Kámélì.
6 Dáfídì sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítori ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dáfídì mu ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
7 Dáfídì sì wí fún Ábíátárì àlùfáà, ọmọ Áhímélékì pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú éfódù fún mi wá níhín-ín yìí. Ábíátarì sì mú éfódù náà wá fún Dáfídì.
8 Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?”Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa: nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”
9 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti ẹgbẹ̀tà ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi ọ̀dọ̀ Bésórì, apákan sì dúró.
10 Ṣùgbọ́n Dáfídì àti irínwó ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, ti wọn kò lè kọjá odò Bésórì sì dúró lẹ́yìn.
11 Wọ́n sì rí ara Éjíbítì kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dáfídì wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu.