8 Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?”Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa: nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”
9 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti ẹgbẹ̀tà ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi ọ̀dọ̀ Bésórì, apákan sì dúró.
10 Ṣùgbọ́n Dáfídì àti irínwó ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, ti wọn kò lè kọjá odò Bésórì sì dúró lẹ́yìn.
11 Wọ́n sì rí ara Éjíbítì kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dáfídì wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu.
12 Wọ́n sì fún un ní àkàrà, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti ṣírí àjàrà gbígbẹ́ méjì: nígbà tí ó sì jẹ ẹ́ tán, ẹ̀mí rẹ̀ sì ṣojí: nítorí pé kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi ní ijọ́ mẹ́ta ní ọ̀sán, àti ní òru.
13 Dáfídì sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?”Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Éjíbítì ni èmi, ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Ámálékì. Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ijọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn.
14 Àwa sì gbé ogun lọ síhà Gúúsù tí ara Kérítì, àti sí ìhà ti Júdà, àti sí ìhà Gúúsù ti Kélẹ́bù; àwa sì kun Síkílágì ní iná.”