1 Sámúẹ́lì 5:3-9 BMY

3 Nígbà tí àwọn ará Ásídódù jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dágónì ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dágónì, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀.

4 Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dágónì sì wá, ó ṣubú ó dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.

5 Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dágónì tàbí àwọn mìíràn tí ó wo inú tẹ́ḿpìlì Dágónì ní Ásídódù fi ń tẹ orí ìloro ẹnu ọ̀nà.

6 Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Ásídódù àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó.

7 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Ásídódù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa ti Ísírẹ́lì kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dágónì ọlọ́run wá.”

8 Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Fílístínì jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì?”Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn Ísírẹ́lì lọ sí Gátì.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

9 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn oníkókó.