1 Nígbà náà àwọn ará Kiriáti-Jéárímù wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Ábínádábù lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásérì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.
2 Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati Jéárímù. Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùn réré ẹkún sí Olúwa.
3 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjòjì àti Áṣitarótì kí ẹ sì farayín jìn fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì”
4 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹra fún Báálì àti Áṣitarótì, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo.
5 Nígbà náà ni, Sámúẹ́lì wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí Mísípà, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.”