2 Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati Jéárímù. Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùn réré ẹkún sí Olúwa.
3 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjòjì àti Áṣitarótì kí ẹ sì farayín jìn fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì”
4 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹra fún Báálì àti Áṣitarótì, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo.
5 Nígbà náà ni, Sámúẹ́lì wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí Mísípà, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.”
6 Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mísípà, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gba ààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa.” Sámúẹ́lì sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Mísípà.
7 Nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé àwọn Ísírẹ́lì ti péjọ ní Mísípà, àwọn aláṣẹ Fílístínì gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Fílístínì.
8 Wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì.”