8 Wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì.”
9 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ọ̀dọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí kè pe Olúwa nítorí ilé Ísírẹ́lì, Olúwa sì dá a lóhùn.
10 Nígbà tí Sámúẹ́lì ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Fílístínì súnmọ́ tòsí láti bá Ísírẹ́lì ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Fílístínì, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
11 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tú jáde láti Mísípà. Wọ́n sì ń lépa àwọn Fílístínì, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Bẹti-Káírì.
12 Sámúẹ́lì mú òkúta kan ó sì fi lé lẹ̀ láàárin Mísípà àti Ṣénì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbẹnésérì, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.”
13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Fílístínì, wọn kò sì wá sí agbégbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́.Ní gbogbo ìgbésí ayé Sámúẹ́lì, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Fílístínì.
14 Àwọn ìlú láti Ékírónì dé Gátì tí àwọn Fílístínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti gbà padà fún Ísírẹ́lì, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Fílístínì. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàárin Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì.