16 Àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀.
17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa se ẹrú u rẹ̀.
18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹyin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”
19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Sámúẹ́lì wọ́n wí pé, “RÁRÁ! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ọba lórí i wa?
20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”
21 Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa.
22 Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.”Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”