17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa se ẹrú u rẹ̀.
18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹyin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”
19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Sámúẹ́lì wọ́n wí pé, “RÁRÁ! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ọba lórí i wa?
20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”
21 Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa.
22 Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.”Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”