1 Sámúẹ́lì 9:12-18 BMY

12 “Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsìn yìí, ó ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.

13 Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbúdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsìn yìí: ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

14 Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Sámúẹ́lì, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

15 Olúwa ti sọ létí Sámúẹ́lì ní ijọ́ kan kí Ṣọ́ọ̀lù ó tó dé pé,

16 “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

17 Nígbà tí Sámúẹ́lì fojú rí Ṣọ́ọ̀lù, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

18 Ṣọ́ọ̀lù sì súnmọ́ Sámúẹ́lì ní ẹnu ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”