31 Nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín tán, wọ́n bọ́ aṣọ ara rẹ̀. Wọ́n tún fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n sì mú un jáde láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
32 Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kíréné tí à ń pè ní Símónì. Wọ́n sì mú ọkùnn náà ní túlààsì láti ru àgbélébùú Jésù.
33 Wọ́n sì jáde lọ sí àdúgbò kan tí à ń pè ní Gọ́lígọ́tà, (èyí tí í ṣe Ibi Agbárí.)
34 Níbẹ̀ ni wọn ti fún un ni ọtí wáìnì tí ó ní egbòogi nínú láti mu. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.
35 Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn.
36 Nígbà náà ni wọ́n jókòó yí i ká. Wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀.
37 Ní òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ohun kan tí ó kà báyìí pé: “ÈYÍ NI JÉSÙ, ỌBA ÀWỌN JÚÙ” síbẹ̀.