21 Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina.
22 Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.”
23 Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba.
24 OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.”
25 Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ.
26 Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀.
27 Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?”