Jẹnẹsisi 25 BM

Àwọn Ọmọ Mìíràn Tí Abrahamu Bí

1 Abrahamu fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura.

2 Ketura bí Simirani, Jokiṣani, Medani, Midiani, Iṣibaku ati Ṣua fún un.

3 Jokiṣani ni baba Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ Dedani ni Aṣurimu, Letuṣimu ati Leumimu.

4 Àwọn ọmọ Midiani ni Efai, Eferi, Hanoku, Abida ati Elidaa. Àwọn ni àwọn ìran tó ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ketura.

5 Ṣugbọn Isaaki ni Abrahamu kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ fún.

6 Ẹ̀bùn ni ó fún gbogbo ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn bí fún un, kí ó tó kú ni ó sì ti ní kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ Isaaki, kí wọ́n lọ máa gbé ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.

Ikú ati Ìsìnkú Abrahamu

7 Ọdún tí Abrahamu gbé láyé jẹ́ aadọsan-an ọdún ó lé marun-un (175),

8 ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́, kí ó tó kú.

9 Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣimaeli, sin òkú rẹ̀ sinu ihò òkúta Makipela, ninu pápá Efuroni, ọmọ Sohari, ará Hiti, níwájú Mamure.

10 Ilẹ̀ tí Abrahamu rà lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n sin ín sí pẹlu Sara aya rẹ̀,

11 Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọrun bukun Isaaki ọmọ rẹ̀. Isaaki sì ń gbé Beeri-lahai-roi.

Àwọn Ìran Iṣimaeli

12 Ìran Iṣimaeli, ọmọ Abrahamu, tí Hagari, ará Ijipti, ọmọ-ọ̀dọ̀ Sara bí fún un nìyí:

13 Àwọn ọmọkunrin Iṣimaeli nìwọ̀nyí bí a ti bí wọn tẹ̀lé ara wọn: Nebaiotu, Kedari, Adibeeli,

14 Mibisamu, Miṣima, Duma, Masa,

15 Hadadi, Tema, Jeturi, Nafiṣi ati Kedema.

16 Àwọn ni ọmọkunrin Iṣimaeli. Wọ́n jẹ́ ọba ẹ̀yà mejila, orúkọ wọn ni wọ́n sì fi ń pe àwọn ìletò ati àgọ́ wọn.

17 Iye ọdún tí Iṣimaeli gbé láyé jẹ́ ọdún mẹtadinlogoje (137). Nígbà tí ó kú a sin ín pẹlu àwọn eniyan rẹ̀.

18 Àwọn ọmọ Iṣimaeli sì ń gbé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Hafila títí dé Ṣuri, tí ó wà ní òdìkejì Ijipti, ní apá Asiria. Wọ́n tẹ̀dó sí òdìkejì àwọn eniyan wọn.

Ìbí Esau ati Jakọbu

19 Ìran Isaaki ọmọ Abrahamu nìyí, Abrahamu ni baba Isaaki.

20 Nígbà tí Isaaki di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Rebeka. Rebeka jẹ́ ọmọ Betueli, ará Aramea, tí ń gbé Padani-aramu, ó sì tún jẹ́ arabinrin Labani, ara Aramea.

21 Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún.

22 Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA.

23 OLUWA wí fún un pé,“Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ,a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà,ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ,èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.”

24 Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́.

25 Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau.

26 Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn.

Esau Ta Ipò Àgbà Rẹ̀

27 Nígbà tí àwọn ọmọ náà dàgbà, Esau di ògbójú ọdẹ, a sì máa lọ sí oko ọdẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ilé ni ó sì máa ń sábà gbé ní tirẹ̀.

28 Isaaki fẹ́ràn Esau nítorí ẹran ìgbẹ́ tí ó máa ń fún un jẹ nígbà gbogbo, ṣugbọn Jakọbu ni Rebeka fẹ́ràn.

29 Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú.

30 Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.)

31 Jakọbu bá dáhùn pé, “Kọ́kọ́ gbé ipò àgbà rẹ fún mi ná.”

32 Esau dá a lóhùn, ó ní, “Ebi ń pa mí kú lọ báyìí, ò ń sọ̀rọ̀ ipò àgbà, kí ni ipò àgbà fẹ́ dà fún mi?”

33 Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi ná.” Esau bá búra fún Jakọbu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gbé ipò àgbà fún un.

34 Jakọbu bá fún Esau ní àkàrà ati ẹ̀bẹ ati ẹ̀fọ́. Nígbà tí Esau jẹ, tí ó mu tán, ó bá tirẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe fi ojú tẹmbẹlu ipò àgbà rẹ̀.