1 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn angẹli meji náà dé ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnubodè ìlú náà. Bí ó ti rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn.
2 Ó ní, “Ẹ̀yin oluwa mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yà sí ilé èmi iranṣẹ yín, kí ẹ ṣan ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sùn ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ìdájí ọ̀la, kí ẹ máa bá tiyín lọ.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Ó tì o! ìta gbangba láàrin ìlú ni a fẹ́ sùn.”
3 Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n gidigidi, wọ́n bá yà sí ilé rẹ̀, ó se àsè fún wọn, ó ṣe àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì jẹun.
4 Ṣugbọn kí àwọn àlejò náà tó sùn, gbogbo àwọn ọkunrin ìlú Sodomu ti dé, àtèwe, àtàgbà, gbogbo wọn dé láìku ẹnìkan, wọ́n yí ilé Lọti po.
5 Wọ́n pe Lọti, wọ́n ní, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí wọ́n dé sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí wà? Kó wọn jáde fún wa, a fẹ́ bá wọn lòpọ̀.”
6 Lọti bá jáde sí wọn, ó ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn àlejò sinu ilé,
7 ó bẹ̀ wọ́n pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí.
8 Ẹ wò ó, mo ní àwọn ọmọbinrin meji tí wọn kò tíì mọ ọkunrin, ẹ jẹ́ kí n kó wọn jáde fún yín, kí ẹ ṣe wọ́n bí ó ti wù yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ọkunrin wọnyi sílẹ̀, nítorí pé inú ilé mi ni wọ́n wọ̀ sí.”
9 Wọ́n dáhùn pé, “Yàgò lọ́nà fún wa, ṣebí àjèjì ni ọ́ ní ilẹ̀ yìí? Ta ni ọ́ tí o fi ń sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa? Bí o kò bá ṣọ́ra, a óo ṣe sí ọ ju bí a ti fẹ́ ṣe sí wọn lọ.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ti Lọti mọ́ ara ìlẹ̀kùn títí ìlẹ̀kùn fi fẹ́rẹ̀ já.
10 Àwọn àjèjì náà bá fa Lọti wọlé, wọ́n ti ìlẹ̀kùn,
11 wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkunrin tí wọ́n ṣù bo ìlẹ̀kùn lóde, àtèwe, àtàgbà wọn, wọ́n wá ojú ọ̀nà títí tí agara fi dá wọn.
12 Àwọn àlejò náà pe Lọti, wọ́n sọ fún un pé, “Bí o bá ní ẹnikẹ́ni ninu ìlú yìí, ìbáà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin tabi ọkọ àwọn ọmọ rẹ, tabi ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tìrẹ ninu ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò níhìn-ín,
13 nítorí pé a ti ṣetán láti pa ìlú yìí run, nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn ará ìlú yìí ti pọ̀ níwájú OLUWA, OLUWA sì ti rán wa láti pa á run.”
14 Lọti bá jáde lọ bá àwọn ọkunrin tí wọ́n fẹ́ àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji sọ́nà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ dìde, ẹ jáde kúrò ninu ìlú yìí nítorí OLUWA fẹ́ pa á run.” Ṣugbọn àwàdà ni ọ̀rọ̀ náà jọ létí wọn.
15 Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Dìde, mú aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ mejeeji tí wọ́n wà níhìn-ín kí o sì jáde, kí o má baà parun pẹlu ìlú yìí.”
16 Ṣugbọn nígbà tí Lọti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ra, àwọn angẹli meji náà mú òun ati aya rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji, wọ́n kó wọn jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, nítorí pé OLUWA ṣàánú Lọti.
17 Nígbà tí wọ́n kó wọn jáde tán, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín; ẹ má ṣe wo ẹ̀yìn rárá, ẹ má sì ṣe dúró níbikíbi ní àfonífojì yìí, ẹ sá gun orí òkè lọ, kí ẹ má baà parun.”
18 Ṣugbọn Lọti wí fún wọn pé, “Áà! Rárá! oluwa mi.
19 Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì kú.
20 Ẹ wò ó, ìlú tí ó wà lọ́hùn-ún nì súnmọ́ tòsí tó láti sálọ, ó sì tún jẹ́ ìlú kékeré. Ẹ jẹ́ kí n sálọ sibẹ, ṣebí ìlú kékeré ni? Ẹ̀mí mi yóo sì là.”
21 OLUWA dáhùn pé, “Ó dára, mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, n kò ní pa ìlú náà run.
22 Ṣe kíá, kí o sálọ sibẹ, nítorí n kò lè ṣe ohunkohun, títí tí o óo fi dé ibẹ̀.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ìlú náà ní Soari.
23 Oòrùn ti yọ nígbà tí Lọti dé Soari.
24 OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora,
25 ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀.
26 Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀.
27 Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Abrahamu lọ sí ibi tí ó ti dúró níwájú OLUWA,
28 ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá.
29 Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun.
30 Nígbà tí ó yá, Lọti jáde kúrò ní Soari, nítorí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ibẹ̀, òun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji bá kó lọ sí orí òkè, wọ́n sì ń gbé inú ihò kan níbẹ̀.
31 Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò, ó ní, “Baba wa ń darúgbó lọ, kò sì sí ọkunrin kan tí yóo fẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn eniyan.
32 Wò ó! Jẹ́ kí á mú baba wa mu ọtí àmupara, kí á sì sùn lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè bá wa lòpọ̀, kí á le tipasẹ̀ rẹ̀ bímọ.”
33 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún baba wọn ní ọtí mu ní alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àkọ́bí wọlé lọ, ó sì mú kí baba wọ́n bá òun lòpọ̀, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde.
34 Ní ọjọ́ keji, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò pé, “Èmi ni mo sùn lọ́dọ̀ baba wa lánàá, jẹ́ kí á tún mú kí ó mu ọtí àmupara lálẹ́ òní, kí ìwọ náà lè wọlé tọ̀ ọ́ lọ, kí ó lè bá ọ lòpọ̀, kí á sì lè bímọ nípasẹ̀ baba wa.”
35 Wọ́n mú kí baba wọn mu ọtí waini ní alẹ́ ọjọ́ náà pẹlu, èyí àbúrò lọ sùn tì í, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde.
36 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lọti mejeeji ṣe lóyún fún baba wọn.
37 Èyí àkọ́bí bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Moabu, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Moabu títí di òní olónìí.
38 Èyí àbúrò náà bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Bẹnami, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Amoni títí di òní olónìí.