Jẹnẹsisi 24 BM

Wọ́n Gbeyawo fún Isaaki

1 Abrahamu ti darúgbó, Ọlọrun sì ti bukun un ní gbogbo ọ̀nà.

2 Abrahamu sọ fún iranṣẹ rẹ̀ tí ó dàgbà jù ninu ilé rẹ̀, ẹni tí í ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó ní, pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi,

3 n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé,

4 ṣugbọn o óo lọ sí ìlú mi, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi, láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”

5 Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Bí ọmọbinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí, ṣé kí n mú ọmọ rẹ pada sí ilẹ̀ tí o ti wá síhìn-ín?”

6 Abrahamu dáhùn pé, “Rárá o! O kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi pada sibẹ.

7 OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.

8 Ṣugbọn bí obinrin náà bá kọ̀ tí kò tẹ̀lé ọ, nígbà náà ọrùn rẹ yóo mọ́ ninu ìbúra tí o búra fún mi, ṣá má ti mú ọmọ mi pada sibẹ.”

9 Iranṣẹ náà bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ abẹ́ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, ó sì búra láti ṣe ohun tí Abrahamu pa láṣẹ fún un.

10 Iranṣẹ náà mú mẹ́wàá ninu àwọn ràkúnmí oluwa rẹ̀, ó gba oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn àtàtà lọ́wọ́ oluwa rẹ̀, ó jáde lọ sí ilẹ̀ Mesopotamia, sí ìlú Nahori.

11 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ní déédé ìgbà tí àwọn obinrin máa ń jáde lọ pọn omi, ó mú kí àwọn ràkúnmí rẹ̀ kúnlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá kànga kan,

12 ó sì gbadura báyìí pé “Ìwọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, jọ̀wọ́, ṣe ọ̀nà mi ní rere lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, oluwa mi.

13 Bí mo ti dúró lẹ́bàá kànga yìí, tí àwọn ọdọmọbinrin ìlú yìí sì ń jáde wá láti pọn omi,

14 jẹ́ kí ọmọbinrin tí mo bá sọ fún pé jọ̀wọ́ sọ ìkòkò omi rẹ kalẹ̀ kí o fún mi ní omi mu, tí ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo sì fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹlu,’ jẹ́ kí olúwarẹ̀ jẹ́ ẹni náà tí o yàn fún Isaaki, iranṣẹ rẹ. Èyí ni n óo fi mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí oluwa mi.”

15 Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu.

16 Arẹwà wundia ni Rebeka, kò sì tíì mọ ọkunrin. Bí ó ti dé, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó pọn omi rẹ̀, ó sì jáde.

17 Iranṣẹ Abrahamu bá sáré tẹ̀lé e, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní omi díẹ̀ mu ninu ìkòkò rẹ.”

18 Ọmọbinrin náà dáhùn pé, “Omi nìyí, oluwa mi.” Ó sì yára gbé ìkòkò rẹ̀ lé ọwọ́ rẹ̀ láti fún un ní omi mu.

19 Bí Rebeka ti fún un ní omi tán, ó ní, “Jẹ́ kí n pọn omi fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu, títí tí gbogbo wọn yóo fi mu omi tán”

20 Kíá, ó ti da omi tí ó kù ninu ìkòkò rẹ̀ sinu agbada tí ẹran fi ń mu omi, ó sáré pada lọ pọn sí i, títí tí gbogbo wọn fi mu omi káríkárí.

21 Ọkunrin náà fọwọ́ lẹ́rán, ó ń wò pé bóyá lóòótọ́ ni OLUWA ti ṣe ọ̀nà òun ní rere ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́.

22 Nígbà tí àwọn ràkúnmí rẹ̀ mu omi tán, tí gbogbo wọn yó, ọkunrin yìí fún un ní òrùka imú tí a fi wúrà ṣe, tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ìdajì ṣekeli, ati ẹ̀gbà ọwọ́ meji tí a fi wúrà ṣe tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ṣekeli wúrà mẹ́wàá.

23 Lẹ́yìn náà, ó bi í pé, “Jọ̀wọ́, kí ni orúkọ baba rẹ? Ǹjẹ́ ààyè ṣì wà ní ilé yín tí a lè wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?”

24 Ó dá a lóhùn, ó ní, “Betueli, ọmọ tí Milika bí fún Nahori ni baba mi.”

25 Ó tún fi kún un pé, “A ní ọpọlọpọ koríko ati oúnjẹ ẹran, ààyè sì wà láti sùn ní ilé wa.”

26 Ọkunrin náà bá tẹríba, ó sì sin OLUWA,

27 ó sọ pé, “Ọpẹ́ ni fún ọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, tí kò gbàgbé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òdodo rẹ̀ sí oluwa mi. Ní tèmi, OLUWA ti tọ́ mi sọ́nà tààrà, sí ilé àwọn ìbátan oluwa mi.”

28 Ọmọbinrin náà bá sáré lọ sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀.

29 Rebeka ní arakunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Labani. Labani yìí ni ó sáré lọ bá ọkunrin náà ní ìdí kànga.

30 Lẹ́yìn tí ó rí òrùka ati ẹ̀gbà ọwọ́ lọ́wọ́ arabinrin rẹ̀, tí ó sì ti gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkunrin náà sọ fún òun, ó lọ bá ọkunrin náà níbi tí ó dúró sí lẹ́bàá kànga pẹlu àwọn ràkúnmí rẹ̀.

31 Labani sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé, ìwọ ẹni tí OLUWA bukun. Èéṣe tí o fi dúró níta gbangba? Mo ti tọ́jú ilé, mo sì ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún àwọn ràkúnmí rẹ.”

32 Ọkunrin náà bá wọlé, Labani sì tú gàárì àwọn ràkúnmí rẹ̀, ó fi koríko ati oúnjẹ fún wọn. Ó fún un ní omi láti fi ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá.

33 Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún un pé kí ó jẹ, ṣugbọn ó wí pé, “N kò ní jẹun títí n óo fi jíṣẹ́ tí wọ́n rán mi.” Labani dáhùn, ó ní, “À ń gbọ́.”

34 Ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Iranṣẹ Abrahamu ni mí,

35 OLUWA ti bukun oluwa mi lọpọlọpọ, ó sì ti di eniyan ńlá. OLUWA ti fún un ní ọpọlọpọ mààlúù ati agbo ẹran, ọpọlọpọ fadaka ati wúrà, ọpọlọpọ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ati ọpọlọpọ ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

36 Sara, aya oluwa mi bí ọmọkunrin kan fún un lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ọmọ yìí sì ni oluwa mi fi ohun gbogbo tí ó ní fún.

37 Oluwa mi mú mi búra pé n kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí òun ń gbé.

38 Ó ni mo gbọdọ̀ wá síhìn-ín, ní ilé baba òun ati sọ́dọ̀ àwọn ẹbí òun láti fẹ́ aya fún ọmọ òun.

39 Mo sì bi oluwa mi nígbà náà pé, ‘bí obinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá ńkọ́?’

40 Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, ‘OLUWA náà tí òun ń fi gbogbo ayé òun sìn yóo rán angẹli rẹ̀ sí mi, yóo sì ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ó ní, mo ṣá gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn eniyan òun ati ní ilé baba òun.

41 Nígbà náà ni ọrùn mi yóo tó mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú fún òun. Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan òun, tí wọ́n bá kọ̀, tí wọn kò jẹ́ kí ọmọbinrin wọn bá mi wá, ọrùn mi yóo mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú.’

42 “Lónìí, bí mo ti dé ìdí kànga tí ó wà lẹ́yìn ìlú, bẹ́ẹ̀ ni mo gbadura sí Ọlọrun, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, bí ó bá jẹ́ pé o ti ṣe ọ̀nà mi ní rere nítòótọ́,

43 bí mo ti dúró nídìí kànga yìí, ọmọbinrin tí ó bá wá pọnmi, tí mo bá sì sọ fún pé, jọ̀wọ́, fún mi lómi mu ninu ìkòkò omi rẹ,

44 tí ó bá wí fún mi pé, “Omi nìyí, mu, n óo sì pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu”, nígbà náà ni n óo mọ̀ pé òun ni obinrin náà tí ìwọ OLUWA ti yàn láti jẹ́ aya ọmọ oluwa mi.’

45 Kí n tó dákẹ́ adura mi, Rebeka yọ pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó sì pọnmi. Mo bá wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi lómi mu.’

46 Kíá ni ó sọ ìkòkò omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, tí ó sì wí pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu.’ Mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí mi lómi mu pẹlu.

47 Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.

48 Nígbà náà ni mo tẹríba, mo sì sin OLUWA, mo yin OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi lógo, ẹni tí ó tọ́ mi sí ọ̀nà tààrà láti wá fẹ́ ọmọ ẹbí oluwa mi fún ọmọ rẹ̀.

49 Nítorí náà, ẹ sọ fún mi bí ẹ óo bá ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu oluwa mi tabi ẹ kò ní ṣe ẹ̀tọ́, kí n lè mọ̀ bí n óo ṣe rìn.”

50 Labani ati Betueli dáhùn pé, “Ati ọ̀dọ̀ OLUWA ni nǹkan yìí ti wá, àwa kò sì ní sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́.

51 Rebeka alára nìyí níwájú rẹ yìí, máa mú un lọ kí ó sì di aya ọmọ oluwa rẹ, bí OLUWA ti wí.”

52 Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA.

53 Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu.

54 Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.”

55 Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!”

56 Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.”

57 Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”

58 Wọ́n bá pe Rebeka, wọ́n bi í pé, “Ṣé o óo máa bá ọkunrin yìí lọ?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ.”

59 Wọ́n bá gbà pé kí Rebeka arabinrin wọn máa lọ, pẹlu olùtọ́jú rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, pẹlu àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá.

60 Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.”

61 Rebeka ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ bá gun ràkúnmí, wọ́n tẹ̀lé ọkunrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni iranṣẹ náà ṣe mú Rebeka lọ.

62 Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Isaaki ti wá láti Beeri-lahai-roi, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nẹgẹbu.

63 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀.

64 Ojú tí Rebeka náà gbé sókè, ó rí Isaaki, ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkúnmí.

65 Ó bi iranṣẹ Abrahamu náà pé, “Ta ni ó ń rìn ninu pápá lọ́ọ̀ọ́kán tí ó ń bọ̀ wá pàdé wa yìí?” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Olúwa mi ni.” Rebeka bá mú ìbòjú rẹ̀, ó dà á bojú.

66 Nígbà tí wọ́n pàdé Isaaki, iranṣẹ náà ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.

67 Isaaki bá mú Rebeka wọ inú àgọ́ Sara ìyá rẹ̀, Rebeka sì di aya rẹ̀, Isaaki sì fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà yìí ni Isaaki kò tó ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́.