1 Ọdún mẹtadinlaadoje (127) ni Sara gbé láyé.
2 Ó kú ní Kiriati Ariba, ní Heburoni, ní ilẹ̀ Kenaani, Abrahamu sọkún, ó sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.
3 Nígbà tí ó yá, Abrahamu dìde níwájú òkú Sara, ó lọ bá àwọn ará Hiti, ó ní,
4 “Àlejò ni mo jẹ́ láàrin yín, ẹ bá mi wá ilẹ̀ ní ìwọ̀nba ninu ilẹ̀ yín tí mo lè máa lò bí itẹ́ òkú, kí n lè sin òkú aya mi yìí, kí ó kúrò nílẹ̀.”
5 Àwọn ará Hiti dá Abrahamu lóhùn, wọ́n ní,
6 “Gbọ́, oluwa wa, olóyè pataki ni o jẹ́ láàrin wa. Sin òkú aya rẹ síbikíbi tí ó bá wù ọ́ jùlọ ninu àwọn itẹ́ òkú wa, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wa tí kò ní fún ọ ní itẹ́ òkú rẹ̀, tabi tí yóo dí ọ lọ́wọ́, pé kí o má ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe.”
7 Abrahamu bá dìde, ó tẹríba níwájú wọn,
8 ó ní, “Bí ẹ bá fẹ́ kí n sin òkú aya mi kúrò nílẹ̀ nítòótọ́, ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì bá mi sọ fún Efuroni ọmọ Sohari,
9 kí ó fún mi ní ihò Makipela, òun ni ó ni ihò náà, ní ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ̀ ni ó wà. Títà ni mo fẹ́ kí ó tà á fún mi ní iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó, lójú gbogbo yín, n óo sì lè máa lo ilẹ̀ náà bí itẹ́ òkú.”
10 Efuroni alára wà ní ìjókòó pẹlu àwọn ará Hiti yòókù, lójú gbogbo àwọn ará ìlú náà ni ó ti dá Abrahamu lóhùn, ó ní,
11 “Rárá o! oluwa mi, gbọ́, mo fún ọ ní ilẹ̀ náà, ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀, lójú gbogbo àwọn eniyan mi ni mo sì ti fún ọ, lọ sin aya rẹ sibẹ.”
12 Nígbà náà ni Abrahamu tẹríba níwájú gbogbo wọn.
13 Ó bá sọ fún Efuroni lójú gbogbo wọn, ó ní, “Ṣugbọn, bí ó bá ti ọkàn rẹ wá, fún mi ní ilẹ̀ náà, kí n sì san owó rẹ̀ fún ọ. Gbà á lọ́wọ́ mi, kí n lè lọ sin aya mi sibẹ.”
14 Efuroni dá Abrahamu lóhùn, ó ní,
15 “Olúwa mi, gbọ́, ilẹ̀ yìí kò ju irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka lọ, èyí kò tó nǹkankan láàrin èmi pẹlu rẹ. Lọ sin òkú aya rẹ.”
16 Abrahamu gbà bí Efuroni ti wí, ó bá wọn irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka tí Efuroni dárúkọ fún un lójú gbogbo wọn, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò ìgbà náà ń lò.
17 Bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ Efuroni ní Makipela, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn Mamure ṣe di ti Abrahamu, ati ihò tí ó wà ninu ilẹ̀ náà, ati gbogbo igi tí ó wà ninu rẹ̀ jákèjádò.
18 Gbogbo àwọn ará Hiti tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ náà di ti Abrahamu.
19 Lẹ́yìn náà, Abrahamu lọ sin òkú Sara sinu ihò ilẹ̀ Makipela, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, ní agbègbè Heburoni ní ilẹ̀ Kenaani.
20 Ilẹ̀ náà ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu láti máa lò bí itẹ́ òkú.