Jẹnẹsisi 27 BM

Isaaki Súre fún Jakọbu

1 Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.”

2 Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi.

3 Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi.

4 Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.”

5 Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́,

6 Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀,

7 pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú.

8 Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ.

9 Lọ sinu agbo ẹran rẹ, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ meji tí ó lọ́ràá wá, kí n fi se irú oúnjẹ aládùn tí baba yín fẹ́ràn fún un,

10 o óo sì lọ gbé e fún baba yín, kí ó jẹ ẹ́, kí ó baà lè súre fún ọ, kí ó tó kú.”

11 Ṣugbọn Jakọbu dá Rebeka ìyá rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Onírun lára ni Esau, ẹ̀gbọ́n mi, n kò sì ní irun lára.

12 Ó ṣeéṣe kí baba mi fi ọwọ́ pa mí lára, yóo wá dàbí ẹni pé mo wá fi ṣe ẹlẹ́yà. Nípa bẹ́ẹ̀ n óo fa ègún sórí ara mi dípò ìre.”

13 Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ègún náà wá sí orí mi, ọmọ mi, ṣá gba ohun tí mo wí, kí o sì lọ mú àwọn ewúrẹ́ náà wá.”

14 Jakọbu bá lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se irú oúnjẹ aládùn tí baba wọn fẹ́ràn.

15 Lẹ́yìn náà Rebeka mú aṣọ Esau, àkọ́bí rẹ̀, tí ó dára jùlọ, tí ó wà nílé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wọ̀ ọ́ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀.

16 Ó mú awọ ewúrẹ́ tí ó pa, ó fi bo ọwọ́ Jakọbu ati ibi tí ó ń dán ní ọrùn rẹ̀,

17 ó sì gbé oúnjẹ aládùn tí ó sè ati àkàrà tí ó tọ́jú fún Jakọbu ọmọ rẹ̀.

18 Ni Jakọbu bá tọ baba rẹ̀ lọ, ó pè é, ó ní, “Baba mi,” Baba rẹ̀ bá dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi, ìwọ ta ni?”

19 Jakọbu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni, mo ti ṣe bí o ti wí, dìde jókòó, kí o sì jẹ ninu ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o lè súre fún mi.”

20 Ṣugbọn Isaaki bi í léèrè pé, “O ti ṣe é tí o fi rí ẹran pa kíákíá bẹ́ẹ̀ ọmọ mi?” Jakọbu dáhùn pé “OLUWA Ọlọrun rẹ ni ó ṣe ọ̀nà mi ní rere.”

21 Isaaki bá wí tìfura-tìfura pé, “Súnmọ́ mi, kí n fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni ọ́ lóòótọ́.”

22 Jakọbu bá súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀, baba rẹ̀ fọwọ́ pa á lára, ó wí pé, “Ọwọ́ Esau ni ọwọ́ yìí, ṣugbọn ohùn Jakọbu ni ohùn yìí.”

23 Kò sì dá Jakọbu mọ̀, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ní irun bíi ti Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó bá súre fún un.

24 Ó bèèrè pé, “Ṣé ìwọ gan-an ni Esau, ọmọ mi?” Jakọbu bá dáhùn pé, “Èmi ni.”

25 Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún.

26 Isaaki baba rẹ̀ bá pè é ó ní, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.”

27 Jakọbu bá súnmọ́ baba rẹ̀, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Baba rẹ̀ gbóòórùn aṣọ rẹ̀, ó sì súre fún un, ó ní,“Òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí OLUWA ti bukun.

28 Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀runati ilẹ̀ tí ó dáraati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini.

29 Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ.Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ,àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ.Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”

Esau Bẹ Isaaki fún Ìre

30 Bí Isaaki ti súre fún Jakọbu tán, Jakọbu fẹ́rẹ̀ má tíì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí Esau ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi ti oko ọdẹ dé.

31 Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.”

32 Isaaki, baba rẹ̀ bi í pé, “Ìwọ ta ni?” Esau bá dá a lóhùn pé, “Èmi ọmọ rẹ ni. Èmi, Esau, àkọ́bí rẹ.”

33 Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.”

34 Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.”

35 Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.”

36 Esau bá dáhùn pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀ nítòótọ́. Ó di ìgbà keji tí yóo fi èrú gba ohun tíí ṣe tèmi. Ó ti kọ́kọ́ gba ipò àgbà lọ́wọ́ mi, ó tún wá jí ìre mi gbà lọ.” Esau bá bèèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Ṣé o kò wá fi ẹyọ ìre kan pamọ́ fún mi ni?”

37 Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”

38 Esau bẹ̀rẹ̀ sí bẹ baba rẹ̀ pé, “Ṣé ìre kan ṣoṣo ni o ní lẹ́nu ni, baba mi? Áà! Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau bá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

39 Nígbà náà ni Isaaki, baba rẹ̀, dá a lóhùn, ó ní,“Níbi tí ilẹ̀ kò ti lọ́ràá ni o óo máa gbé,níbi tí kò sí ìrì ọ̀run.

40 Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè, arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn,ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà,o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”

41 Nítorí irú ìre tí baba wọn sú fún Esau yìí ni Esau ṣe kórìíra Jakọbu. Esau dá ara rẹ̀ lọ́kàn le ó ní, “Ìgbà mélòó ni ó kù tí baba wa yóo fi kú? Bí ó bá ti kú ni n óo pa Jakọbu, arakunrin mi.”

42 Ṣugbọn wọ́n sọ ohun tí Esau, àkọ́bí Rebeka ń wí fún Rebeka ìyá rẹ̀. Rebeka bá ranṣẹ pe Jakọbu, ó wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀, Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pẹlu ìpinnu láti pa ọ́.

43 Nítorí náà, ọmọ mi, gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, wá gbéra kí o sálọ bá Labani, arakunrin mi, ní Harani.

44 Kí o sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ títí tí inú tí ń bí arakunrin rẹ yóo fi rọ̀,

45 tí inú rẹ̀ yóo yọ́, tí yóo sì gbàgbé ohun tí o ti ṣe sí i, n óo wá ranṣẹ pè ọ́ pada nígbà náà. Mo ha gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ ẹ̀yin mejeeji lọ́jọ́ kan náà bí?”

Isaaki Rán Jakọbu Lọ sọ́dọ̀ Labani

46 Rebeka sọ fún Isaaki, ó ní, “Ọ̀rọ̀ àwọn obinrin Hiti wọnyi mú kí ayé sú mi. Bí Jakọbu bá lọ fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin ará Hiti, irú àwọn obinrin ilẹ̀ yìí, irú ire wo ni ó tún kù fún mi láyé mọ́?”