1 Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde kúrò ní Ijipti, ó pada lọ sí Nẹgẹbu pẹlu aya rẹ̀, ati Lọti ati ohun gbogbo tí ó ní.
2 Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ.
3 Nígbà tí ó yá, ó kúrò ní Nẹgẹbu, ó ń lọ sí Bẹtẹli, ó dé ibi tí ó kọ́kọ́ pàgọ́ sí
4 láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA.
5 Lọti tí ó bá Abramu lọ náà ní ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo mààlúù ati ọpọlọpọ àgọ́ fún ìdílé rẹ̀ ati àwọn iranṣẹ rẹ̀.
6 Ẹran ọ̀sìn àwọn mejeeji pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ náà kò fi láàyè tó mọ́ fún wọn láti jọ máa gbé pọ̀.
7 Ìjà sì ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn darandaran Abramu ati àwọn ti Lọti. Ní àkókò náà, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi ń gbé ilẹ̀ náà.
8 Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá?
9 Ilẹ̀ ló lọ jaburata níwájú rẹ yìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á takété sí ara wa. Bí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún, bí o bá sì lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.”
10 Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run.
11 Lọti bá yan gbogbo agbègbè odò Jọdani fún ara rẹ̀, ó sì lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe takété sí ara wọn.
12 Abramu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì ń gbé ààrin àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè odò Jọdani, ó pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu.
13 Àwọn ará Sodomu yìí jẹ́ eniyan burúkú, wọn ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA lọpọlọpọ.
14 Lẹ́yìn tí Lọti ti kúrò lọ́dọ̀ Abramu, OLUWA sọ fún Abramu pé, “Gbé ojú rẹ sókè, kí o wò ó láti ibi tí o wà yìí, títí lọ sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, tún wò ó lọ sí ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn.
15 Gbogbo ilẹ̀ tí ò ń wò yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún títí lae.
16 N óo mú kí àwọn ọmọ rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tí yóo fi jẹ́ pé, àfi ẹni tí ó bá lè ka iye erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóo lè kà wọ́n.
17 Dìde, kí o rìn jákèjádò ilẹ̀ náà, nítorí pé ìwọ ni n óo fún.”
18 Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA.