1 Josẹfu bá wọlé lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi ati àwọn arakunrin mi ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, pẹlu gbogbo agbo ẹran ati agbo mààlúù wọn, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní, wọ́n sì wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.”
2 Ó mú marun-un ninu àwọn arakunrin rẹ̀, ó fi wọ́n han Farao.
3 Farao bi àwọn arakunrin rẹ̀ léèrè irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.Wọ́n dá Farao lóhùn pé, darandaran ni àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn.
4 Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni.
5 Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Ọ̀dọ̀ rẹ ni baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ wá.
6 Wo ilẹ̀ Ijipti láti òkè dé ilẹ̀, ibikíbi tí o bá rí i pé ó dára jùlọ ninu gbogbo ilẹ̀ náà ni kí o fi baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ sí. Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, bí o bá sì mọ èyíkéyìí ninu wọn tí ó lè bojútó àwọn ẹran ọ̀sìn dáradára, fi ṣe alabojuto àwọn ẹran ọ̀sìn mi.”
7 Josẹfu bá mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé láti fihan Farao, Jakọbu sì súre fún Farao.
8 Farao bi Jakọbu pé, “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́ báyìí?”
9 Jakọbu dá a lóhùn pé, “Ọjọ́ orí mi jẹ́ aadoje (130) ọdún. Ọjọ́ orí mi kò tó nǹkan rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti rí ọpọlọpọ ibi. Ọjọ́ orí mi kò tíì dé ibìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn baba mi.”
10 Jakọbu súre fún Farao ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
11 Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ.
12 Josẹfu pèsè ohun jíjẹ fún baba ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí olukuluku wọn ń bọ́.
13 Ìyàn náà mú tóbẹ́ẹ̀ tí ìdààmú bá gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani nítorí pé kò sí oúnjẹ rárá ní ilẹ̀ Kenaani.
14 Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao.
15 Nígbà tí kò sí owó mọ́ rárá ní ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani, gbogbo àwọn ará Ijipti tọ Josẹfu lọ, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran báyìí títí tí a óo fi kú? Kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá.”
16 Josẹfu bá dá wọn lóhùn pé, “Bí kò bá sí owó lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ kó àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, n óo sì fun yín ní oúnjẹ dípò wọn.”
17 Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà.
18 Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa.
19 Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.”
20 Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao,
21 ó sì sọ àwọn eniyan náà di ẹrú rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ijipti.
22 Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn.
23 Josẹfu sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Àtẹ̀yin, àtilẹ̀ yín, láti òní lọ, mo ra gbogbo yín fún Farao. Irúgbìn nìyí, ẹ lọ gbìn ín sinu oko yín.
24 Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.”
25 Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.”
26 Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao.
27 Israẹli ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ní Goṣeni, wọ́n sì ní ọpọlọpọ ohun ìní níbẹ̀, wọ́n bímọ lémọ, wọ́n sì pọ̀ sí i gidigidi.
28 Ọdún mẹtadinlogun ni Jakọbu gbé sí i ní ilẹ̀ Ijipti, gbogbo ọdún tí ó gbé láyé sì jẹ́ ọdún mẹtadinlaadọjọ (147).
29 Nígbà tí àkókò tí Jakọbu yóo kú súnmọ́ tòsí, ó pe Josẹfu ọmọ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Wá, ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, kí o sì ṣèlérí pé o óo ṣe olóòótọ́ sí mi, o kò sì ní dà mí. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ijipti,
30 ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.”Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.”
31 Jakọbu ní kí Josẹfu búra fún òun, Josẹfu sì búra fún un. Nígbà náà ni Jakọbu tẹríba lórí ibùsùn rẹ̀.