1 Josẹfu pàṣẹ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Ẹ di ọkà kún àpò àwọn ọkunrin wọnyi, bí wọ́n bá ti lè rù tó, kí ẹ sì fi owó olukuluku wọn sí ẹnu àpò rẹ̀,
2 kí ẹ wá fi ife fadaka mi sí ẹnu àpò èyí àbíkẹ́yìn wọn, pẹlu owó tí ó fi ra ọkà.” Ọkunrin náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un.
3 Bí ilẹ̀ ọjọ́ keji ti mọ́, wọ́n ní kí àwọn arakunrin Josẹfu máa lọ ati àwọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.
4 Nígbà tí wọn kò tíì rìn jìnnà sí ìlú, Josẹfu sọ fún alabojuto ilé rẹ̀ pé, “Gbéra, sáré tẹ̀lé àwọn ọkunrin náà, nígbà tí o bá bá wọn, wí fún wọn pé, ‘Èéṣe tí ẹ fi fi ibi sú olóore? Èéṣe tí ẹ fi jí ife fadaka ọ̀gá mi?
5 Ife yìí ni ọ̀gá mi fi ń mu omi, ife yìí kan náà ni ó sì fi ń woṣẹ́, ọ̀ràn ńlá gan-an ni ẹ dá yìí.’ ”
6 Nígbà tí ó lé wọn bá, ó wí fún wọn bí Josẹfu ti kọ́ ọ.
7 Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Èéṣe tí o fi ń sọ̀rọ̀ sí wa báyìí? Kí á má rí i, pé àwa iranṣẹ rẹ ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀.
8 Ṣé o ranti pé owó tí a bá lẹ́nu àpò wa, a mú un pada ti ilẹ̀ Kenaani wá fún ọ? Kí ni ìbá dé tí a óo fi jí fadaka tabi wúrà ní ilé ọ̀gá rẹ?
9 Bí wọ́n bá bá a lọ́wọ́ èyíkéyìí ninu àwa iranṣẹ rẹ, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀, kí àwa yòókù sì di ẹrú rẹ.”
10 Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ ti wí gan-an ni yóo rí. Ọwọ́ ẹni tí a bá ti bá a ni yóo di ẹrú mi, kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin yòókù rárá.”
11 Gbogbo wọn bá sọ àpò wọn kalẹ̀, wọ́n tú wọn.
12 Iranṣẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àpò wọn, ó bẹ̀rẹ̀ lórí àpò èyí àgbà patapata, títí dé orí ti àbíkẹ́yìn wọn, wọ́n bá ife náà ninu ẹrù Bẹnjamini.
13 Wọ́n fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, olukuluku wọn bá di ẹrù rẹ̀ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, wọ́n pada lọ sí ààrin ìlú.
14 Nígbà tí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀ pada dé ilé Josẹfu, ó ṣì wà nílé, wọ́n bá dọ̀bálẹ̀ gbalaja níwájú rẹ̀.
15 Josẹfu bi wọ́n léèrè, ó ní, “Irú kí ni ẹ dánwò yìí? Ó jọ bí ẹni pé ẹ kò lérò pé irú mi lè woṣẹ́ ni?”
16 Juda dá a lóhùn, ó ní, “Kí ni a rí tí a lè wí fún ọ, oluwa mi? Ọ̀rọ̀ wo ni ó lè dùn lẹ́nu wa? Ọṣẹ wo ni a lè fi wẹ̀, tí a fi lè mọ́? Ọlọrun ti rí ẹ̀bi àwa iranṣẹ rẹ. Wò ó, a di ẹrú rẹ, oluwa mi, ati àwa ati ẹni tí wọ́n bá ife náà lọ́wọ́ rẹ̀.”
17 Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Ẹnìkan ṣoṣo tí wọ́n ká ife náà mọ́ lọ́wọ́ ni yóo di ẹrú mi, ní tiyín, ẹ máa pada tọ baba yín lọ ní alaafia.”
18 Juda bá tọ̀ ọ́ lọ, ó ní, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, jẹ́ kí n sọ gbolohun ọ̀rọ̀ kan, má jẹ́ kí inú bí ọ sí èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí kò sí ìyàtọ̀, bíi Farao ni o rí.
19 Oluwa mi, ranti pé o bi àwa iranṣẹ rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ ní baba tabi arakunrin mìíràn?’
20 A sì dá oluwa mi lóhùn pé, ‘A ní baba, ó ti di arúgbó, a sì ní arakunrin kan pẹlu, tí baba yìí fi arúgbó ara bí, ati pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ṣoṣo ni ó kù lọ́mọ ìyá tirẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀.’
21 O sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé kí á mú un tọ̀ ọ́ wá, kí o lè fi ojú rí i.
22 A sì sọ fún ọ pé, ‘Ọmọ náà kò lè fi baba rẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé bí ó bá fi baba rẹ̀ sílẹ̀, baba rẹ̀ yóo kú.’
23 O bá sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé bí àbíkẹ́yìn wa patapata kò bá bá wa wá, a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ mọ́.
24 “Nígbà tí a pada dé ọ̀dọ̀ baba wa, iranṣẹ rẹ, a rò fún un bí o ti wí.
25 Nígbà tí ó ní kí á tún lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá,
26 a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá.
27 Baba wa sọ fún wa pé a mọ̀ pé ọkunrin meji ni Rakẹli, aya òun bí fún òun,
28 ọ̀kan fi òun sílẹ̀, òun sì wí pé, dájúdájú, ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, òun kò sì tíì fi ojú òun kàn án láti ìgbà náà.
29 Ó ní bí a bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ òun, bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, pẹlu arúgbó ara òun yìí, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo pa òun.
30 “Nítorí náà, bí mo bá pada dé ọ̀dọ̀ baba mi tí n kò sì mú ọmọdekunrin náà lọ́wọ́, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọmọdekunrin yìí gan-an ni ó fi ẹ̀mí tẹ̀,
31 bí kò bá rí i pẹlu wa, kíkú ni yóo kú. Yóo sì wá jẹ́ pé àwa ni a fa ìbànújẹ́ fún baba wa, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ìbànújẹ́ yìí ni yóo sì pa á.
32 Èmi ni mo dúró fún ọmọdekunrin náà lọ́dọ̀ baba wa, mo wí fún un pé, ‘Bí n kò bá mú ọmọ yìí pada, ẹ̀bi rẹ̀ yóo wà lórí mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.’
33 Nígbà tí ọ̀rọ̀ wá rí bí ó ti rí yìí, oluwa mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi di ẹrú rẹ dípò ọmọdekunrin yìí, jẹ́ kí òun máa bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pada lọ.
34 Báwo ni n óo ṣe pada dé iwájú baba mi láìmú ọmọ náà lọ́wọ́? Ẹ̀rù ohun burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí baba mi, ń bà mí.”