1 Josẹfu dojúbo òkú baba rẹ̀ lójú, ó sọkún, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.
2 Lẹ́yìn náà, Josẹfu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn pé kí wọ́n fi òògùn tí wọ́n fi máa ń tọ́jú òkú, tí kì í fíí bàjẹ́, tọ́jú òkú baba òun. Wọ́n fi òògùn yìí tọ́jú òkú Jakọbu.
3 Ogoji ọjọ́ gbáko ni àwọn oníṣègùn máa fi ń tọ́jú irú òkú bẹ́ẹ̀. Àwọn ará Ijipti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún aadọrin ọjọ́.
4 Nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Josẹfu sọ fún àwọn ará ilé Farao pé, “Ẹ jọ̀wọ́, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ bá mi sọ fún Farao pé,
5 baba mi mú mi búra nígbà tí àtikú rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, pé, ‘Nígbà tí mo bá kú, ninu ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani, ni kí ẹ sin mí sí.’ Nítorí náà, kí Farao jọ̀wọ́, fún mi láàyè kí n lọ sin òkú baba mi, n óo sì tún pada wá.”
6 Farao dáhùn, ó ní, “Lọ sin òkú baba rẹ gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún un.”
7 Josẹfu lọ sin òkú baba rẹ̀, gbogbo àwọn iranṣẹ Farao sì bá a lọ, ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà ààfin ọba, ati gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú Ijipti,
8 ati gbogbo ìdílé Josẹfu àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀, àfi àwọn ọmọde, àwọn agbo ẹran, ati àwọn mààlúù nìkan ni ó kù sí ilẹ̀ Goṣeni.
9 Kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin bá a lọ pẹlu, àwọn eniyan náà pọ̀ lọpọlọpọ.
10 Nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Atadi, níwájú Jọdani, wọ́n pohùnréré ẹkún, Josẹfu sì ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ meje.
11 Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani.
12 Àwọn ọmọ Jakọbu sin òkú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wọn.
13 Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú.
14 Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ.
15 Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n ní, “Ó ṣeéṣe kí Josẹfu kórìíra wa, kí ó sì gbẹ̀san gbogbo ibi tí a ti ṣe sí i.”
16 Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé,
17 ‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún.
18 Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.”
19 Ṣugbọn Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, èmi kì í ṣe Ọlọrun.
20 Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí.
21 Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle.
22 Josẹfu sì ń gbé ilẹ̀ Ijipti, òun ati ìdílé baba rẹ̀, ó gbé aadọfa (110) ọdún láyé.
23 Josẹfu rí ìran kẹta ninu àwọn ọmọ Efuraimu. Àwọn ọmọ tí Makiri ọmọ Manase bí, ọwọ́ Josẹfu ni ó bí wọn sí pẹlu.
24 Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Àtikú mi kù sí dẹ̀dẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun yóo máa tọ́jú yín, yóo sì mu yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu.”
25 Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra fún un pé, nígbà tí Ọlọrun bá mú wọn pada sí ilẹ̀ Kenaani, wọn yóo kó egungun òun lọ́wọ́ lọ.
26 Josẹfu kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n fi òògùn tọ́jú òkú rẹ̀ kí ó má baà bàjẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sinu pósí ní ilẹ̀ Ijipti.