1 Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?”
2 Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà,
3 àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”
4 Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá,
5 Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.”
6 Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́.
7 Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí.
8 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà.
9 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”
10 Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”
11 Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”
12 Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
13 OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”
14 OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
15 N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà,ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”
16 Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé,“N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún,ninu ìrora ni o óo máa bímọ.Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí,òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”
17 Ó sọ fún Adamu, pé,“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
18 Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ,ewéko ni o óo sì máa jẹ.
19 Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.Erùpẹ̀ ni ọ́,o óo sì pada di erùpẹ̀.”
20 Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan.
21 OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.
22 Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”
23 Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.
24 Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.