1 Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, Ọlọrun dán Abrahamu wò, ó ní, “Abrahamu!” Abrahamu dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
2 Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.”
3 Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu.
4 Ní ọjọ́ kẹta, bí Abrahamu ti wo ọ̀kánkán, ó rí ibi tí Ọlọrun júwe fún un ní òkèèrè.
5 Abrahamu bá sọ fún àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e, ó ní, “Ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níhìn-ín, èmi ati ọmọ yìí yóo rìn siwaju díẹ̀, láti lọ sin Ọlọ́run, a óo sì pada wá bá yín.”
6 Abrahamu gbé igi ẹbọ sísun náà lé Isaaki, ọmọ rẹ̀ lórí, ó mú ọ̀bẹ ati iná lọ́wọ́. Àwọn mejeeji jọ ń lọ.
7 Isaaki bá pe Abrahamu, baba rẹ̀, ó ní, “Baba mi.” Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ni, ọmọ mi?” Isaaki ní, “Wò ó, a rí iná ati igi, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun dà?”
8 Abrahamu dá a lóhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni yóo pèsè, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun náà.” Àwọn mejeeji tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ.
9 Nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ọlọrun júwe fún Abrahamu, ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó to igi sórí pẹpẹ náà, ó di Isaaki ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó bá gbé e ka orí igi lórí pẹpẹ tí ó tẹ́.
10 Abrahamu nawọ́ mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀.
11 Ṣugbọn angẹli OLUWA pè é láti òkè ọ̀run, ó ní, “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.”
12 Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.”
13 Bí Abrahamu ti gbé orí sókè, tí ó wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí àgbò kan tí ó fi ìwo kọ́ pàǹtí. Ó lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀.
14 Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.”
15 Angẹli OLUWA tún pe Abrahamu láti òkè ọ̀run ní ìgbà keji,
16 ó ní, “Mo fi ara mi búra pé nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ kan ṣoṣo,
17 n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà.
18 Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”
19 Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀.
20 Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sọ fún Abrahamu pé Milika ti bímọ fún Nahori arakunrin rẹ̀.
21 Usi ni àkọ́bí, Busi ni wọ́n bí tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà Kemueli tíí ṣe baba Aramu.
22 Lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Kesedi, Haso, Pilidaṣi, Jidilafi ati Betueli.
23 Betueli ni baba Rebeka. Àwọn mẹjẹẹjọ yìí ni Milika bí fún Nahori, arakunrin Abrahamu.
24 Nahori tún ní obinrin mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Reuma, òun ni ó bí Teba, Gahamu, Tahaṣi, ati Mahaka fún Nahori.