1 Nígbà kan èdè kan ṣoṣo ni ó wà láyé, ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan ni gbogbo wọ́n sì ń lò.
2 Bí àwọn eniyan ṣe ń ṣí káàkiri ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní agbègbè Babiloni, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ.
3 Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á ṣe bíríkì, kí á sì sun wọ́n jiná dáradára.” Bíríkì ni wọ́n lò dípò òkúta, wọ́n sì lo ọ̀dà ilẹ̀ dípò ọ̀rọ̀.
4 Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìlú ńlá kan, kí á sì kọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan tí orí rẹ̀ yóo kan ojú ọ̀run gbọ̀ngbọ̀n, kí á baà lè di olókìkí, kí á má baà fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ ayé.”
5 OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú tí àwọn ọmọ eniyan ń tẹ̀dó ati ilé ìṣọ́ gíga tí wọn ń kọ́.
6 OLUWA wí pé, “Ọ̀kan ni gbogbo àwọn eniyan wọnyi, èdè kan ṣoṣo ni wọ́n sì ń sọ, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí wọn yóo ṣe ni, kò sì ní sí ohun kan tí wọn bá dáwọ́lé láti ṣe tí yóo dẹtì fún wọn.
7 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ bá wọn, kí á dà wọ́n ní èdè rú, kí wọn má baà gbọ́ èdè ara wọn mọ́.”
8 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì.
9 Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe pe orúkọ ìlú náà ní Babeli, nítorí níbẹ̀ ni OLUWA ti da èdè gbogbo ayé rú, láti ibẹ̀ ni ó sì ti fọ́n wọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ ayé.
10 Àkọsílẹ̀ ìran Ṣemu nìyí: ọdún keji lẹ́yìn tí ìkún omi ṣẹlẹ̀, tí Ṣemu di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ni ó bí Apakiṣadi.
11 Lẹ́yìn tí Ṣemu bí Apakiṣadi tán, ó tún gbé ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
12 Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela.
13 Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
14 Nígbà tí Ṣela di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.
15 Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
16 Nígbà tí Eberi di ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ni ó bí Pelegi.
17 Eberi tún gbé ojilenirinwo ó dín mẹ́wàá (430) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Pelegi tán, ó tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
18 Nígbà tí Pelegi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.
19 Ó tún gbé igba ọdún ó lé mẹsan-an (209) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
20 Nígbà tí Reu di ẹni ọdún mejilelọgbọn ni ó bí Serugi.
21 Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
22 Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.
23 Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
24 Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra.
25 Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
26 Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani.
27 Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti.
28 Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí.
29 Abramu ati Nahori ní iyawo, Sarai ni orúkọ iyawo Abramu, orúkọ iyawo ti Nahori sì ni Milika, ọmọbinrin Harani. Harani ni baba Milika ati Isika.
30 Àgàn ni Sarai, kò bímọ.
31 Tẹra mú Abramu ọmọ rẹ̀, ati Lọti, ọmọ Harani tíí ṣe ọmọ Tẹra, ati Sarai aya Abramu, ó kó gbogbo wọn jáde kúrò ní Uri ti ilẹ̀ Kalidea, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé Harani, wọ́n tẹ̀dó sibẹ.
32 Nígbà tí Tẹra di ẹni igba ọdún ó lé marun-un (205), ó kú ní ilẹ̀ Harani.