1 Àkọsílẹ̀ ìran Adamu nìyí: Nígbà tí Ọlọrun dá eniyan, ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀.
2 Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan.
3 Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.
4 Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
5 Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú.
6 Nígbà tí Seti di ẹni ọdún marundinlaadọfa (105), ó bí Enọṣi.
7 Lẹ́yìn tí ó bí Enọṣi, ó tún gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé meje (807) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
8 Gbogbo ọdún tí Seti gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejila (912), kí ó tó kú.
9 Nígbà tí Enọṣi di ẹni aadọrun-un ọdún, ó bí Kenani.
10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé mẹẹdogun (815) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
11 Gbogbo ọdún tí Enọṣi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé marun-un (905) kí ó tó kú.
12 Nígbà tí Kenani di ẹni aadọrin ọdún, ó bí Mahalaleli.
13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ogoji (840) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
14 Gbogbo ọdún tí Kenani gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mẹ́wàá (910) kí ó tó kú.
15 Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi.
16 Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
17 Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú.
18 Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku.
19 Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
20 Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú.
21 Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela.
22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
23 Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365).
24 Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ.
25 Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki.
26 Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
27 Gbogbo ọdún tí Metusela gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mọkandinlaadọrin (969) kí ó tó kú.
28 Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan.
29 Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.”
30 Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
31 Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú.
32 Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti.