Jẹnẹsisi 31 BM

Jakọbu Sá kúrò lọ́dọ̀ Labani

1 Jakọbu gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń sọ pé òun ti gba gbogbo ohun tíí ṣe ti baba wọn, ninu ohun ìní baba wọn ni òun sì ti kó gbogbo ọrọ̀ òun jọ.

2 Jakọbu pàápàá kíyèsí i pé Labani kò fi ojurere wo òun mọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

3 Nígbà náà ni OLUWA sọ fún Jakọbu pé, “Pada lọ sí ilẹ̀ baba rẹ ati ti àwọn ìbátan rẹ, n óo sì wà pẹlu rẹ.”

4 Jakọbu bá ranṣẹ pe Rakẹli ati Lea sinu pápá níbi tí agbo ẹran rẹ̀ wà.

5 Ó wí fún wọn pé, “Mo ṣàkíyèsí pé baba yín kò fi ojurere wò mí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́, ṣugbọn Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi.

6 Ẹ̀yin náà mọ̀ pé gbogbo agbára mi ni mo ti fi sin baba yín,

7 sibẹ, baba yín rẹ́ mi jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà mi pada nígbà mẹ́wàá, ṣugbọn Ọlọrun kò gbà fún un láti pa mí lára.

8 Bí ó bá wí pé àwọn ẹran tí ó ní funfun tóótòòtóó ni yóo jẹ́ owó ọ̀yà mi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí onífunfun tóótòòtóó. Bí ó bá sì wí pé, àwọn ẹran tí ó bá ní àwọ̀ tí ó dàbí adíkálà ni yóo jẹ́ tèmi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà.

9 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gba gbogbo ẹran baba yín tí ó sì fi wọ́n fún mi.

10 “Ní àkókò tí àwọn ẹran náà ń gùn, mo rí i lójú àlá pé àwọn òbúkọ tí wọn ń gun àwọn ẹran jẹ́ àwọn tí àwọ̀ wọn dàbí ti adíkálà ati àwọn onífunfun tóótòòtóó ati àwọn abilà.

11 Angẹli Ọlọrun bá sọ fún mi ní ojú àlá náà, ó ní, ‘Jakọbu.’ Mo dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’

12 Angẹli Ọlọrun bá sọ pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò ó pé gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran inú agbo jẹ́ aláwọ̀ adíkálà ati onífunfun tóótòòtóó ati abilà, nítorí mo ti rí gbogbo ohun tí Labani ń ṣe sí ọ.

13 Èmi ni Ọlọrun Bẹtẹli, níbi tí o ti ta òróró sórí òkúta tí o sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi. Dìde nisinsinyii, kí o jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pada sí ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí ọ.’ ”

14 Ni Rakẹli ati Lea bá dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ogún kan tilẹ̀ tún kù fún wa ní ilé baba wa mọ́?

15 Ǹjẹ́ kò ti kà wá kún àjèjì? Nítorí pé ó ti tà wá, ó sì ti ná owó tí ó gbà lórí wa tán.

16 Ti àwa ati àwọn ọmọ wa ni ohun ìní gbogbo tí Ọlọrun gbà lọ́wọ́ baba wa jẹ́, nítorí náà, gbogbo ohun tí Ọlọrun bá sọ fún ọ láti ṣe, ṣe é.”

17 Jakọbu bá dìde, ó gbé àwọn ọmọ ati àwọn aya rẹ̀ gun ràkúnmí.

18 Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani.

19 Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó.

20 Ọgbọ́n ni Jakọbu lò fún Labani ará Aramea, nítorí pé Jakọbu kò sọ fún un pé òun fẹ́ sálọ.

21 Ó dìde, ó kó gbogbo ohun tí ó ní, ó sá gòkè odò Yufurate, ó doríkọ ọ̀nà agbègbè olókè Gileadi.

Labani Lépa Jakọbu

22 Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n sọ fún Labani pé Jakọbu ti sálọ,

23 ó kó àwọn ìbátan rẹ̀, ó sì tọpa rẹ̀ fún ọjọ́ meje, ó bá a ní agbègbè olókè Gileadi.

24 Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún Labani ará Aramea lóru lójú àlá, ó ní, “Ṣọ́ra, má bá Jakọbu sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.”

25 Labani lé Jakọbu bá níbi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní orí òkè náà, Labani ati àwọn ìbátan rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí agbègbè olókè Gileadi.

26 Labani pe Jakọbu, ó ní, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí? O tàn mí jẹ, o sì kó àwọn ọmọbinrin mi sá bí ẹrú tí wọ́n kó lójú ogun.

27 Èéṣe tí o fi tàn mí jẹ, tí o yọ́ lọ láìsọ fún mi? Ṣebí ǹ bá fi ayọ̀, ati orin ati ìlù ati hapu sìn ọ́.

28 Èéṣe tí o kò fún mi ní anfaani láti fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi lẹ́nu kí n fi dágbére fún wọn? Ìwà òmùgọ̀ ni o hù yìí.

29 Mo ní agbára láti ṣe ọ́ níbi, ṣugbọn Ọlọrun baba rẹ bá mi sọ̀rọ̀ ní òru àná pé kí n ṣọ́ra, kí n má bá ọ sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.

30 Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?”

31 Jakọbu bá dá Labani lóhùn, ó ní, “Ẹ̀rù ni ó bà mí, mo rò pé o óo fi ipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi.

32 Ní ti àwọn ère oriṣa rẹ, bí o bá bá a lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Níwájú gbogbo ìbátan wa, tọ́ka sí ohunkohun tí ó bá jẹ́ tìrẹ ninu gbogbo ohun tí ó wà lọ́dọ̀ mi, kí o sì mú un.” Jakọbu kò mọ̀ rárá pé Rakẹli ni ó jí àwọn ère oriṣa Labani kó.

33 Labani bá wá inú àgọ́ Jakọbu, ati ti Lea ati ti àwọn iranṣẹbinrin mejeeji, ṣugbọn kò rí àwọn ère oriṣa rẹ̀. Bí ó ti jáde ninu àgọ́ Lea ni ó lọ sí ti Rakẹli.

34 Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn.

35 Rakẹli wí fún baba rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, má bínú pé n kò dìde lójú kan tí mo jókòó sí, mò ń ṣe nǹkan oṣù mi lọ́wọ́ ni.” Bẹ́ẹ̀ ni Labani ṣe wá àwọn ère oriṣa rẹ̀ títí, ṣugbọn kò rí wọn.

36 Inú wá bí Jakọbu, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Labani, ó ní, “Kí ni mo ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ tí o fi ń tọpa mi kíkankíkan bẹ́ẹ̀?

37 Nígbà tí o tú gbogbo ẹrù mi palẹ̀, àwọn nǹkan rẹ wo ni o rí níbẹ̀? Kó o kalẹ̀ níwájú àwọn ìbátan mi ati àwọn ìbátan rẹ, kí wọ́n lè dájọ́ láàrin wa.

38 Fún ogún ọdún tí mo fi bá ọ gbé, ewúrẹ́ rẹ kan tabi aguntan kan kò sọnù rí, bẹ́ẹ̀ ni n kò jí àgbò rẹ kan pajẹ rí.

39 Èyí tí ẹranko burúkú bá pajẹ tí n kò bá gbé òkú rẹ̀ wá fún ọ, èmi ni mò ń fara mọ́ ọn. O máa ń gba ààrọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ mi, ìbáà jẹ́ ní òru ni ó sọnù tabi ní ọ̀sán.

40 Bẹ́ẹ̀ ni mò ń wà ninu oòrùn lọ́sàn-án ati ninu òtútù lóru, oorun kò sì sí lójú mi.

41 Ó di ogún ọdún tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, mo fi ọdún mẹrinla sìn ọ́ nítorí àwọn ọmọbinrin rẹ, ati ọdún mẹfa fún agbo ẹran rẹ. Ìgbà mẹ́wàá ni o sì pa owó ọ̀yà mi dà.

42 Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi, àní, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun tí Isaaki ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, láìsí àní àní, ìwọ ìbá ti lé mi lọ lọ́wọ́ òfo kó tó di àkókò yìí. Ọlọrun rí ìyà mi ati iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó fi kìlọ̀ fún ọ ní alẹ́ àná.”

Labani ati Jakọbu Dá Majẹmu

43 Labani bá dá Jakọbu lóhùn, ó ní, “Èmi ni mo ni àwọn ọmọbinrin wọnyi, tèmi sì ni àwọn ọmọ wọnyi pẹlu, èmi náà ni mo ni àwọn agbo ẹran, àní gbogbo ohun tí ò ń wò wọnyi, èmi tí mo ni wọ́n nìyí. Ṣugbọn kí ni mo lè ṣe lónìí sí àwọn ọmọbinrin mi wọnyi ati sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí?

44 Ó dára, jẹ́ kí èmi pẹlu rẹ dá majẹmu, kí majẹmu náà sì jẹ́ ẹ̀rí láàrin àwa mejeeji.”

45 Jakọbu bá gbé òkúta kan, ó fi sọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n.

46 Ó sì sọ fún àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n kó òkúta jọ. Wọ́n sì kó òkúta jọ, wọ́n fi ṣe òkítì ńlá kan, gbogbo wọn bá jọ jẹun níbi òkítì náà.

47 Labani sọ ibẹ̀ ní Jegari Sahaduta, ṣugbọn Jakọbu pè é ní Galeedi.

48 Labani wí pé, “Òkítì yìí ni ohun ẹ̀rí láàrin èmi pẹlu rẹ lónìí.” Nítorí náà ó sọ ọ́ ní Galeedi.

49 Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa.

50 Bí o bá fi ìyà jẹ àwọn ọmọbinrin mi, tabi o tún fẹ́ obinrin mìíràn kún àwọn ọmọbinrin mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan pẹlu wa, ranti o, Ọlọrun ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa mejeeji.”

51 Labani bá sọ fún Jakọbu pé, “Wo òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí, tí mo ti gbé kalẹ̀ láàrin àwa mejeeji.

52 Òkítì yìí ati ọ̀wọ̀n yìí sì ni ẹ̀rí pẹlu pé n kò ní kọjá òkítì yìí láti wá gbógun tì ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà kò ní kọjá òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí láti wá gbógun tì mí.

53 Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù.

54 Jakọbu bá rúbọ lórí òkè náà, ó pe àwọn ìbátan rẹ̀ láti jẹun, wọ́n sì wà lórí òkè náà ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

55 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu láti dágbére fún wọn, ó súre fún wọn, ó sì pada sílé.