1 Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín.
2 Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín.
3 Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi,ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ,tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi.
4 Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn,o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀,o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.
5 Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin,ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn.
6 Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀,ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́.Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan,wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.
7 Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le,ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n.N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu,n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli.
8 Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́,apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ;àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ.
9 Juda dàbí kinniun,tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán,a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀.Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ,kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ.
10 Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda,arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba,títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín;gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
11 Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà,yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára,bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀.
12 Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini,eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà.
13 “Sebuluni yóo máa gbé etí òkun,ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye,Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀.
14 “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbáratí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀.
15 Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dáraati pé ilẹ̀ náà dára,ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù,ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú.
16 Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli.
17 Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà,ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ,kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn.
18 Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa.
19 Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù,ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o,bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada.
20 Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀,oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde.
21 Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri,tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà.
22 Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri.
23 Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan,wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi,
24 sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì,apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i.Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun,(ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà,tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli),
25 Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá,yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀,ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.
26 Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ,kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu,ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀.
27 “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa,a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀,ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.”
28 Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un.
29 Jakọbu kìlọ̀ fún wọn, ó ní, “Mo ṣetán, mò ń re ibi àgbà á rè, inú ibojì tí wọ́n sin àwọn baba mi sí, ninu ihò òkúta tí ó wà ninu ilẹ̀ Efuroni, ará Hiti, ni kí ẹ sin mí sí.
30 Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú.
31 Níbẹ̀ ni wọ́n sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni wọ́n sin Isaaki sí ati Rebeka aya rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi náà sì sin Lea sí.
32 Lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n ti ra ilẹ̀ náà ati ihò òkúta tí ó wà ninu rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ sin mí sí.”
33 Nígbà tí Jakọbu parí ìkìlọ̀ tí ó ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ pada sí orí ibùsùn rẹ̀, ó dùbúlẹ̀, lẹ́yìn náà ó mí kanlẹ̀, ó sì re ibi tí àgbà á rè.