1 Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, OLUWA bá Abramu sọ̀rọ̀ lójú ìran, ó ní, “Má bẹ̀rù Abramu, n óo dáàbò bò ọ́, èrè rẹ yóo sì pọ̀ pupọ.”
2 Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni?
3 O kò fún mi lọ́mọ, ẹrú tí wọ́n bí ninu ilé mi ni yóo di àrólé mi!”
4 OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe ọkunrin yìí ni yóo jẹ́ àrólé rẹ, ọmọ bíbí inú rẹ ni yóo jẹ́ àrólé rẹ.”
5 OLUWA bá mú un jáde, ó sì sọ fún un pé, “Wo ojú ọ̀run, kí o ka gbogbo ìràwọ̀ tí ó wà níbẹ̀ bí o bá lè kà wọ́n.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo ṣe pọ̀ tó.”
6 Abramu gba OLUWA gbọ́, OLUWA sì kà á sí olódodo.
7 Ó sọ fún un pé “Èmi ni OLUWA tí ó mú ọ jáde láti ìlú Uri, ní ilẹ̀ Kalidea, láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ ní ohun ìní.”
8 Ṣugbọn Abramu bèèrè pé, “OLUWA Ọlọrun, báwo ni n óo ṣe mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóo jẹ́ tèmi?”
9 OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “Mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù ọlọ́dún mẹta kan, ati ewúrẹ́ ọlọ́dún mẹta kan, ati àgbò ọlọ́dún mẹta kan, ati àdàbà kan ati ọmọ ẹyẹlé kan wá.”
10 Ó kó gbogbo wọn wá fún OLUWA, ó là wọ́n sí meji meji, ó sì tẹ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn lọ, ṣugbọn kò la àdàbà ati ẹyẹlé náà.
11 Nígbà tí àwọn ẹyẹ tí wọ́n máa ń jẹ òkú ẹran rábàbà wá sí ibi tí Abramu to àwọn ẹran náà sí, ó lé wọn.
12 Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀.
13 Nígbà náà ni OLUWA sọ fún un pé, “Mọ̀ dájúdájú pé àwọn ọmọ rẹ yóo lọ gbé ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, wọn yóo di ẹrú níbẹ̀, àwọn ará ibẹ̀ yóo sì mú wọn sìn fún irinwo (400) ọdún.
14 Ṣugbọn n óo mú ìdájọ́ wá sórí orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóo sìn. Àṣẹ̀yìnwá, àṣẹ̀yìnbọ̀, wọn yóo jáde kúrò níbẹ̀ pẹlu ọpọlọpọ dúkìá.
15 Ìwọ náà yóo dàgbà, o óo di arúgbó, ní ọjọ́ àtisùn rẹ, ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ ni o óo kú.
16 Atọmọdọmọ rẹ kẹrin ni yóo pada wá síhìn-ín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò tíì kún ojú òṣùnwọ̀n.”
17 Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ṣú, kòkò iná tí ó ń rú èéfín ati ìtùfù tí ń jò lálá kan kọjá láàrin àwọn ẹran tí Abramu tò sílẹ̀.
18 Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate,
19 ilẹ̀ àwọn ará Keni, ti àwọn ará Kenisi, ti àwọn ará Kadimoni,
20 ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Refaimu,
21 ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Kenaani, ti àwọn ará Girigaṣi ati ti àwọn ará Jebusi.”